352 Yoruba Proverbs, Sayings And Translations - Yoruba Project - 210 - 219 - #AdebanjiOsanyingbemi #OlayinkaCarew #edeYoruba #oweYoruba

 210. Ọlọ́run ò fẹ́ irọ́; ọmọ èyàn ò fẹ́ òdodo; bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ ò pé mẹ́ta. 


God hates lies; man hates truths; yet there is no third option in a discourse.


Stick with the truth, even when there are no easy options!211. Wọ́n ní, “Afọ́jú, o ò tanná alẹ́.” Ó ní àtọ̀sán àtòru, èwo lòún rí níbẹ?


People said, “Blind man, you did not light a lamp.” He asked, night or day, which one would his eyes register?


One should not waste one's efforts in procuring things one cannot use.
212. Ọlọ́gbọ́n dorí ẹja mú; òmùgọ́ dìrù-u ẹ̀ mú.


The wise person grabs a fish by the head; the fool grabs it by the tail fin.


The wise person knows better than a fool the best way to handle a situation.213. Ọ̀pọ̀ ló fẹ́ láàpa láì lápá, bí èèyàn ò sì lápá, kò leè láàpa. 


Many want to make a mark without effort, yet without effort, no marks can be made.


Nothing ventured, nothing gained; there's always a price tag: be willing to pay it!214. Adìyẹ ńjẹ yangan, ó ńmu omi ó ńgbé ókúta mì, ó tún ńsunkún àìléyín; ṣé òbúkọ tó léyín ńjẹ irin ni? 


Hens eat corns, drink water, and swallow stones, yet lament lacking teeth; do goats, with teeth, chew pieces of iron (with theirs)?


Contentment is it; greed breeds stress!215. Ọlọgbọ́n ńdẹ ihò, ọ̀mọ̀rànán dúró tì í; ọlọgbọ́n ní “Háà, ó jáde!”Ọ̀mọ̀rán ní “Háà, mo kì í!”Ọlọgbọ́n ní “Kí lo kì?” Ọ̀mọ̀rán ní “Kí nìwọ náà-á ló jáde?”


The cunning man is watching a hole, and the knowledgeable person is standing by him; the cunning man exclaims, “Ha, it has sprung out!” The knowledgeable person responds, “Ha, I have grabbed it!” The cunning person asks, “What did you grab?” The knowledgeable person asks in turn, “What did you say sprang out?”


Two matched wits are in contest.216. Jùrù-fẹ̀fẹ̀ jùrù-fẹ̀fẹ̀, ewúrẹ́ wọ ilé àpọn jùrù-fẹ̀fẹ̀; kí làpọ́n rí jẹ tí yó kù sílẹ̀ féwúrẹ́?


Busily wagging tail, busily wagging tail, a goat enters a bachelor's house busily wagging its tail; what does a bachelor have to eat whose left-over the goat can have?


One wastes one's time expecting some largesse from a destitute person.217. Kàkà kí ọmọdé pàgbà láyò, àgbà a fi ọgbọ́n àgbà gbé e.


Instead of permitting defeat by a child in a game, an elder should resort to elderly wiles.


An elder should protect his face and standing by all means available.218. Kì í jẹ́ kí etí ẹni di kì í jẹ kí inú ẹni dùn.


Whatever keeps one from being deaf to certain things keeps one from being happy.


One should learn to turn a deaf ear to certain things for the sake of one's peace of mind.
219. Ìwò-o ọlọgbọ́n ò jọ ti aṣiwèrè.


The way a wise person looks at things is different from the way an imbecile does.


A wise person considers matter in a more rational way than an imbecile does.


Purchase the book:   https://amzn.to/4bIllq3


Watch the videos?


Buy similar books - https://amzn.to/3UDAhP6


https://amzn.to/3WGy8oE


Other books by Jack Lookman 


We do Affiliate Marketing, and earn commissions for each sale, at no additional cost to you.


Ire o (I wish you blessings)


Ire kabiti (I wish you loads of blessings) From Jack Lookman and the Team at Yoruba Project 

Comments

Popular posts from this blog

352 Yoruba Proverbs, Sayings And Translations - Yoruba Project - 1-9 - #oweYoruba #edeYoruba #ireo #Irekabiti #AdebanjiOsanyingbemi

352 Yoruba Proverbs, Sayings And Translations - Yoruba Project - 20 - 29 -#ireo #Irekabiti #edeYoruba #oweYoruba #AdebanjiOsanyingbemi

352 Yoruba Proverbs, Sayings And Translations - Yoruba Project - 10 - 19 - #ireo #Irekabiti #edeYoruba #oweYoruba #AdebanjiOsanyingbemi