Posts

Showing posts from April, 2024

352 Yoruba Proverbs, Sayings And Translations - Yoruba Project - 70 - 79 - #AdebanjiOsanyingbemi #JackLookman #oweYoruba #edeYoruba #ireo

  70. Ẹní bá pé kí àkàlà má jòkú, ojú-u rẹ̀ lẹyẹ ńkọ́kọ́ yọ jẹ. Whoever says the ground-hornbill should not eat carrion, he or she will be the first to lose his or her eyes to the bird. Whoever tries to prevent the inevitable will be trampled in the process of its occurring. 71. Ènìyàn kì í mọ iyì ohun tó ní, à fi tó bá sọ ọ́ nù. We seldom appreciate what we have, until we lose the thing. Take nothing desired for granted: we lose, sometimes permanently, whatever we take for granted; treasure whatever you wish to keep. 72. A kì í gbé ẹran erin lérí ká máa fẹsẹ̀ wa ihò ìrẹ̀. One does not carry elephant meat on one's head and dig cricket holes with one's big toe. If one is blessed with plenty, one should not keep chasing after trifles. 73. Ojú ọba ayé ló fọ́; tọ̀rún là kedere, ó ńwo aṣebi. Only the king of this earth is blind; that of heaven is wide-eyed, watching evil doers. God sees all acts of wickedness that may be hidden from earthly authorities. 7

352 Yoruba Proverbs, Sayings And Translations - Yoruba Project - 60 - 69 #AdebanjiOsanyingbemi #JackLookman #oweYoruba #edeYoruba #ireo

  60. Jẹ́ kí ńfìdí hẹẹ́, ni àlejò fi ńti onílé sóde.   Let me just hang in here, is how the guest takes over the house from the host. Think well about that inch you want to give, it may well become a mile: be perceptive, be circumspect. 61. Aṣọ à-fọ̀-fún ò jẹ́ ká mọ olówó. Clothes washed clean make identifying the rich person impossible. A poor person who looks to his or her appearance looks rich. 62. Ojú la fi ḿmọ àísí epo; ẹnu la fi ḿmọ àìsíyọ̀; ọbẹ̀ tí ò bá lépo nínú òkèèrè la ti ḿmọ̀ ọ́. It is with the eyes that one tells the absence of palm-oil; it is with the mouth that one determines the absence of salt; if a stew lacks oil, it is the eyes that will tell. In some matters the evidence of the eyes is enough to tell one all one needs to know. 63. Àìsanra tó ajá ológìnní kì í ṣe ti àìjẹun ká'nú; bí ìran rẹ̀ ṣe mọ ni. The smaller frame of cats' relative to dogs isn't for want of food; that's cats' genetic makeup. Appearance can be deceptiv

352 Yoruba Proverbs, Sayings And Translations - Yoruba Project - 50 - 59 #ireo #Irekabiti #edeYoruba #oweYoruba #AdebanjiOsanyingbemi

  50. Tí ọdẹ bá ro ìṣẹ́, tó bá ro ìyà, tó bá pa ẹran, kò ní fún ẹnìkan jẹ.   If a hunter were to consider the hardship of his (hunting) expedition, he won't share his games with anyone. Any kind of giving is tough (and quite often sacrificial); be appreciative! 51. Adániwáyé ò gbàgbé ẹnìkan; àìmàsìkò ló ńdààmú ẹ̀dá.  God, the Creator, hasn't forgotten anyone; ignorance of divine timing is what makes us fret. The best is yet to come; keep hope alive! 52. Aláṣejù ní ńgbẹ́bọ kọjá ìdí èṣù; a-gbé-sàráà-kọjá-a-Mọ́ṣáláṣí. It is an immoderate person who carries his offering past Èṣù's shrine; one-who-carries-his-alms-past-the-Mosque. It is a grievous fault not to observe discreet limits. 53. Bí abẹ́rẹ́ bí abẹ́rẹ́ lèèyàn ńṣèké; ọjọ́ tó bá tóbi tó ọkọ́ tí a fi ńroko ní ńpani. Like a needle, like a needle, one compiles falsehood; the day it is as big as the hoe one uses on a farm, that is the day it kills one. Small falsehoods eventually grow into a habit pow