Posts

Showing posts from June, 2024

352 Yoruba Proverbs Sayings And Translations - Yoruba Project 310 - 319 - Adebanji Osanyingbemi - Olayinka Carew - Jack Lookman - ede Yoruba

  310. À-rí-ì-gbọdọ̀-wí, à-rí-ì-gbọdọ̀-fọ̀ ni ikú awo. Something seen but unmentionable, something seen but unspeakable is the death of a guardian of the mysteries. The eyes sometimes see things that are too sacred for the mouth to mention. 311. Àrùn là ńwó a kì í wokú. One treats a disease; one does not treat death. We should attend to problems before they become unmanageable. 312. Aláwàdà ló lè ṣọkọ òṣónú; ẹni tí kò lẹ́nu mímú tete ò lè ṣọkọ alápẹpẹ. Only a good-humored person can make a good husband for an ill-humored woman; a person whose mouth is not sharp cannot make a good husband for a hyperactive woman. Incompatible natures cannot make a good marriage. 313. Àlá tí ajá bá lá, inú ajá ní ńgbé. Whatever dream the dog dreams remains inside the dog. Keep your own counsel. 314. Baálé ilé kú, wọ́n fi olókùnrùn rọ́lé; ẹkún ńgorí ẹkún. The man of the house died and they put an invalid in his place; weeping climbs upon weeping. People known to be unsuitab

352 Yoruba Proverbs Sayings And Translations - Yoruba Project 300 - 309 - Adebanji Osanyingbemi - Olayinka Carew - Jack Lookman #ede Yoruba

  300. Ogún kì í pọ̀ ká pín fún aládùúgbò. The inheritance is never so abundant that one shares it with neighbors. However abundantly one is blessed one should manage one's resources wisely. 301. Ẹ̀ jáwọ́ l'ápọ́n tì ò yọ́ , ẹ́ lọ́ gbómí ílá kànáá Stop with the seed of the bush mango and go with the okra( which draw better) Desist from what is not profitable to you and find a better alternative 302. Tí èwurẹ́ bá jẹ́ lọ́ á pádà wá sílé, bí aguntán bá jẹ́ lọ́ a pádà wá sílé When the goat strays it still comes back home when the sheep strays it comes back home No matter how long we sojourn we will definitely come back to our comfort zone 303. Ọlọ́tọ̀ọ́ ní tòun ọ̀tọ̀; ìyá ẹ̀-ẹ́ kú nílé, o gbé e lọ sin sóko. Ọlọ́tọ̀ says his ways are different; his mother dies at home and he takes her to the farm for burial. The unconventional person will always do things differently. 304. Tí igi bá ré lu igi ti òkè rẹ la ńkọkọ gbé. If a tree falls on another, we remove